Fún ayẹyẹ Àyàjọ́ Ọjọ́ Èdè Abínibí L’ágbàyé fún 2018 tí UNESCO yà sọ́tọ̀, a pè yín láti kópa nínú ìdíje tuntun alárinrin yìí!
Àyàjọ́ Ọjọ́ Èdè Abínibí L’ágbàyé ni a yà sọ́tọ̀ láti polongo àti gbé lárugẹ àwọn èdè àti àṣà oríṣiríṣi l’ágbàyé, pàápàá jùlọ àwọn èdè abínibí, àwọn èdè kékèké, àwọn èdè àbáláyé, àti àwọn èdè tí wọn ti wà ní ipò ewu.
Ìdíje Rẹ: Darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn kí o sì kópa nípa ṣíṣẹ̀dá àwòrán ẹ̀fẹ̀ kan ní èdè abínibí rẹ, fi hashtag kan kún-un, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lágbàyé.
Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa Ìdíje, jọ̀wọ́ kàn sí: Mother Language Meme Challenge